Ìtumọ̀ ògigí ní èdè Yorùbá:

ògigí

Ohũ̀ /do re mi/

ɔ̀ɾɔ̀-oɾúkɔ

  • irú igbá abihò tí àwọn adẹgbá fí ń dẹ àláàkàṣà ní òkun; ihò kékeré tí wọ́n fi ọ̀pọ̀rọ̀ lu já igbá nọ́ọ̀ ni kí omi léè rọ̀ọ́ jáde bí a bá fàá láti òkun láì jẹ̀ẹ́ kí àwọn àláàkàṣà nọ́ọ̀ sá kúrò

    Ògigí tí o fún mi ni mo fi dẹ àwọn àláàkàṣà wọ̀nyìí.
    • Mo fi igbá lu igbá, fi àwo lu àwo láti lọ dẹ ẹja, báyìí ni mo mu àwọ̀n, ìgèrè, àti ògigí sínú àpò-ọdẹ, mo rè òkun.